Pe àwọn Ọlọ́pàá Ọba Oman lórí ìlà yìí

800 77 444

Tí wọ́n bá mú ọ wá sí Ómàn lábẹ́ àwọn ìlérí èké, àti pé àwọn ipò iṣẹ́ rẹ yàtọ̀ sí ohun tí o nírètí, o lè jẹ́ olùfaragbà ìfiniṣowò àìtọ́.

Ṣé èyíkèyí nínú ìwọ̀nyí níí ṣe pẹ̀lú rẹ?

  • Wọ́n tí gba ìwé ìrìnnà mí lọ.
  • Owó mi kéré ju ohun tí wọ́n ṣèlérí nínú ìwé ìgbanisiṣẹ́ mi.
  • Wọ́n n fí ipá mú mi láti ṣe àfikún iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí ju ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé ìgbanisiṣẹ́ mi láìsí àfikún owó mi.
  • Wọn kìí fún mi ní ààyè ìsinmi ní àárín ọ̀sẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni wọn kìí san owó fún iṣẹ́ tí mo bá ṣe ní àwọn ọjọ́ ìsinmi mi.
  • Agbanísíṣẹ́ mi sọ fún mi pé mo jẹ́ wọ́n lówó fun ṣíṣe agbátẹ̀ru èmi àti ìwé ìrìnnà mi.
  • Agbanísíṣẹ́ mi sọ pe mo jẹ wọn ni gbese fun ibùgbé, ìtọ́jú ìlera, tàbí óúnjẹ.
  • Mo jẹ agbátẹrù mi tàbí ilé-iṣẹ́ ìgbanisiṣẹ́ kan ní gbèsè fún mímú wá sí orílẹ̀-èdè yìí.
  • Agbanisíṣẹ́ mi ti halẹ̀ mọ́ mi pẹ̀lú dídá mi padà bí mo bá fi ẹjọ́ òun sun àwọn  ọlọ́pàá tàbí ẹ̀ka alábòjutó ọrọ́ iṣẹ́ nípa ipò iṣẹ́ mi.
  • Àwọn ará ilé ibi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ ń bá mi ní àjọ̀ṣepọ̀ àìtọ̀ tàbí wọ́n ń fi ọwọ́ bà mí lára lọ́nà àìtọ́.
  • Agbanisiṣẹ́ mi máa ń nà mí.
  • Wọ́n ti halẹ̀ mọ́ mi pẹ̀lú ìjàǹbá.
  • Wọ́n fipá mú mi láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin.
  • Mo fẹ́ dẹ́kun síṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó sùgbọ́n ọ̀gá mi kò ní gbà mí láyè.

Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè jẹ́ olùfaragbà ìfiniṣòwò àìtọ́.

Kí o sì rántí pé , ẹrànjẹ  ni ọ́ o kìí ṣe ọ̀daràn.

Àwọn Ọlọ́pàá Ọba Oman ṣetán láti tẹ́tí sí ọ. Wọ́n kọ́ wọn láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn èèyàn bí tìrẹ. Wọ́n lè dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ àwon agbaniṣíṣẹ́. Wọ́n lè fi òpin sí ìbànújẹ́ rẹ.

Kíni ó yẹ kí n ṣe?

Tí wọ́n bá gbà ọ́ láyè láti jáde fúnra rẹ, bẹ ìkan lára àwọn àgọ́ Ọlọ́pàá Ọba Oman wò, kí o sì ṣọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣí ọ fún wọn. O sì lè sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ kan kí ó bá ọ kàn sí wọn.

 Pe àwọn Ọlọ́pàá Ọba Oman lórí ìlà yìí

800 77 444

Ọ̀fẹ́ ni ìpè. Àwọn ọlọ́pàá máa ń sọ èdè Lárúbáwá àti Gẹ̀ẹ́sì.

Bí ìwọ kò bá lè sọ èdè Lárúbáwá tàbí Gẹ̀ẹ́sì, sọ fún ẹnìkan tí ó bá lè ṣe bẹ́ẹ̀ pé kí o bá ọ pè wọ́n.

Kíni yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

Àwọn Ọlọ́pàá Ọba Oman yóò tọpinpin ejọ́ rẹ.  Wọ́n le mú ọ lọ sí ibi ààbò tó dájú fún ààbò àti ìtọ̀jú rẹ. Àwọn òsìṣẹ́ arannilọ́wọ́ yóò ri dájú pé o ní ààbò tó péye, wọn yóò sì pèsè ibùgbé, ìtọ́jú ìlera, àti àwọn ǹǹkan mííràn tí o bá nílò gẹ́gẹ́ bí àtìpó. Gbogbo àwọn ǹǹkan wọ̀nyìí ni ó jẹ́ ọ̀fẹ́ láìsí ìdíyelé kànkan sí ọ.